Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 2:30-37 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni,wọn kò gba ẹ̀kọ́.Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun,bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.

31. Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ.Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli;tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri?Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé,‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri;a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’

32. Ṣé ọmọbinrin lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀?Tabi iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lè gbàgbé àwọn aṣọ rẹ̀?Sibẹ ẹ ti gbàgbé mi tipẹ́.

33. “Ẹ mọ oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí eniyan fi í wá olólùfẹ́ kiri,tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ ti fi ìrìnkurìn yínkọ́ àwọn obinrin oníwà burúkú.

34. Ẹ̀jẹ̀ àwọn talaka tí kò ṣẹ̀, wà létí aṣọ yín;bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bá wọn níbi tí wọ́n ti ń fọ́lé.Gbogbo èyí wà bẹ́ẹ̀,

35. sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọwọ́ wa mọ́;dájúdájú, OLUWA ti dá ọwọ́ ibinu rẹ̀ dúró lára wa.’Ẹ wò ó! N óo dá yín lẹ́jọ́,nítorí ẹ̀ ń sọ pé ẹ kò dẹ́ṣẹ̀.

36. Ẹ̀ ń fi ara yín wọ́lẹ̀ káàkiri;ẹ̀ ń yà síhìn-ín sọ́hùn-ún!Bí Asiria ti dójú tì yín,bẹ́ẹ̀ ni Ijipti náà yóo dójú tì yín.

37. Ẹ óo ká ọwọ́ lérí ninígbà tí ẹ óo bá jáde níbẹ̀.Nítorí OLUWA ti kọ àwọn tí ẹ gbójúlé,wọn kò sì ní ṣe yín níre.”

Ka pipe ipin Jeremaya 2