Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 2:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún mi pé,

2. “Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí.

3. Israẹli jẹ́ mímọ́ fún OLUWAÒun ni àkọ́so èso rẹ̀.Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ninu àkọ́so èso yìí di ẹlẹ́bi;ibi sì dé bá wọn.Èmi OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

4. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ilé Jakọbu, ati gbogbo ìdílé Israẹli.

5. OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán?

6. Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà,ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti,tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já,ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun,ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri,ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá,tí ẹnikẹ́ni kì í gbé?

7. Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá,pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀,ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́,ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.

8. Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí,àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi,àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali,wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn.

9. “Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́,n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.”OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

10. Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká,tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní,bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí.

11. Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́?Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn,wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀.

12. Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run,kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.”

Ka pipe ipin Jeremaya 2