Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 18:16-22 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Wọ́n sọ ilẹ̀ wọn di ohun ẹ̀rù ati ohun àrípòṣé títí lae.Gbogbo àwọn tí wọn bá gba ibẹ̀ kọjá ni ẹ̀rù yóo máa bà,tí wọn yóo sì máa mi orí.

17. N óo fọ́n wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn.Ẹ̀yìn ni n óo kọ sí wọn lọ́jọ́ àjálù,wọn kò ní rí ojú mi.”

18. Wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹ wá, kí á gbìmọ̀ ibi sí Jeremaya, nítorí pé òfin kò ní parun lọ́dọ̀ àwọn alufaa, ìmọ̀ràn kò ní tán lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sì ní ṣàì máa wà lẹ́nu àwọn wolii. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa pa á, ẹ má sì jẹ́ kí á fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kankan.”

19. Mo bá gbadura pe,“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA,kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi.

20. Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere?Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi.Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere,kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn.

21. Nítorí náà ìyàn ni kí ó pa àwọn ọmọ wọn,kí ogun pa wọ́n,kí àwọn aya wọn di aláìlọ́mọ ati opó,kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọkunrin wọn,kí idà ọ̀tá sì pa àwọn ọ̀dọ̀ wọn lójú ogun.

22. Kí igbe ẹkún ó sọ ninu ilé wọn,nígbà tí o bá mú àwọn apanirun wá sórí wọn lójijì;nítorí pé wọ́n wa kòtò láti mú mi,wọ́n dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi.

Ka pipe ipin Jeremaya 18