Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 17:5-20 BIBELI MIMỌ (BM)

5. OLUWA ní,“Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan,tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀;tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA.

6. Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀,nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i.Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà,ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.

7. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò,tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò.Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé,nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini.Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀,nígbà gbogbo ni yóo sì máa so.

9. “Ọkàn eniyan kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀;ta ni ó lè mọ èrò ọkàn eniyan?

10. Èmi OLUWA ni èmi máa ń wádìí èrò eniyan,tí èmi sì máa ń yẹ ọkàn eniyan wò,láti san án fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀,ati gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

11. Bí àparò tíí pa ẹyin ẹlẹ́yinbẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ.Ọrọ̀ yóo lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ lọ́sàn-án gangan,nígbẹ̀yìn yóo di òmùgọ̀.

12. Ìtẹ́ ògo tí a tẹ́ sí ibi gíga láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ibi mímọ́ wa.

13. OLUWA, ìwọ ni Israẹli gbójú lé,ojú yóo ti gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀.A óo kọ orúkọ àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ sórí ilẹ̀,yóo sì parẹ́,nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA, orísun omi ìyè, sílẹ̀.

14. Wò mí sàn, OLUWA, ara mi yóo sì dá,gbà mí, n óo sì bọ́ ninu ewu.Nítorí pé ìwọ ni mò ń yìn.

15. Wò ó! Wọ́n ń bi mí pé,“Níbo ni gbogbo ìhàlẹ̀ OLUWA já sí?Jẹ́ kí ó ṣẹ, kí á rí i!”

16. N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o rán ibi sí wọn,bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ ọjọ́ ibi fún wọn.OLUWA, o mọ̀ bẹ́ẹ̀.Ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde kò tún lè ṣàjèjì sí ọ.

17. Má di ohun ẹ̀rù fún mi,nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ ibi.

18. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi,ṣugbọn kí ojú má tì mí.Jẹ́ kí ìpayà bá wọn,ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà.Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa.

19. OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ dúró ní ẹnubodè Bẹnjamini níbí, tí àwọn ọba Juda máa ń gbà wọlé, tí wọn sìí gbà jáde; ati ní gbogbo ẹnubodè Jerusalẹmu,

20. kí o wí pé, ‘Ẹ gbọ́ bí OLUWA ti wí, ẹ̀yin ọba Juda, ati gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé.

Ka pipe ipin Jeremaya 17