Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 13:20-23 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹ gbé ojú sókè,kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá.Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà,àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà?

21. Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́,tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí?Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí?

22. Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé,“Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?”Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín,tí a sì jẹ yín níyà.

23. Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada?Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù?Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere;ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára.

Ka pipe ipin Jeremaya 13