Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 13:19-27 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Wọ́n ti sé ìlẹ̀kùn odi àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbukò sì sí ẹni tí yóo ṣí wọn.A ti kó gbogbo Juda lọ sí ìgbèkùn,gbogbo wọn pátá ni a ti kó lọ.

20. Ẹ gbé ojú sókè,kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá.Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà,àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà?

21. Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́,tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí?Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí?

22. Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé,“Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?”Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín,tí a sì jẹ yín níyà.

23. Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada?Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù?Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere;ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára.

24. N óo fọn yín ká bí ìyàngbòtí afẹ́fẹ́ láti inú aṣálẹ̀ ń fẹ́ kiri.

25. Èyí ni ìpín yín,ìpín tí mo ti yàn fun yín,nítorí pé ẹ ti gbàgbé èmi OLUWA, ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ọlọrun èké.

26. Èmi gan-an ni n óo ká aṣọ lára yín,n óo sì fi bò yín lójú, kí ayé lè rí ìhòòhò yín.

27. Mo ti rí ìwà ìbàjẹ́ yín,gbogbo ìwà àgbèrè yín, bí ẹ tí ń yan ká bí akọ ẹṣin,ati ìwà ìṣekúṣe yín ní orí àwọn òkè ninu pápá.Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gbé!Yóo ti pẹ́ tó kí á tó wẹ̀ yín mọ́?

Ka pipe ipin Jeremaya 13