Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 10:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nítorí OLUWA wí pé,“Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò.N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn,kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.”

19. Mo gbé, nítorí mo fara gbọgbẹ́!Ọgbẹ́ náà sì pọ̀.Ṣugbọn mo sọ fún ara mi pé,“Ìyà gan-an ni èyí jẹ́ fún mi,mo sì gbọdọ̀ fara dà á.”

20. Àgọ́ mi ti wó, gbogbo okùn rẹ̀ sì ti já.Àwọn ọmọ mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́.Kò sí ẹni tí yóo máa bá mi pa àgọ́ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóo máa bá mi ta aṣọ àgọ́ mi.

21. Nítorí pé òmùgọ̀ ni àwọn olùṣọ́-aguntan,wọn kò sì ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA,nítorí náà wọn kò ṣe àṣeyọrí,tí gbogbo agbo wọn sì fi túká.

22. Ẹ gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ kan! Ó ń tàn kálẹ̀!Ìdàrúdàpọ̀ ńlá ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,tí yóo sọ àwọn ìlú Juda di ahoroyóo sì di ibùgbé àwọn ajáko.

23. OLUWA, mo mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀dá kò sí ní ọwọ́ ara rẹ̀.Kò sí ní ìkáwọ́ ẹni tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.

24. Tọ́ mi sọ́nà, OLUWA,ṣugbọn lọ́nà ẹ̀tọ́ ni kí o bá mi wí,kì í ṣe pẹlu ibinu rẹ,kí o má baà sọ mí di ẹni ilẹ̀.

25. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ ọ́,ni kí o bínú sí kí ó pọ̀,ati àwọn tí wọn kì í jọ́sìn ní orúkọ rẹ;nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹrun patapata,wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.

Ka pipe ipin Jeremaya 10