Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 10:14-19 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀;gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì,nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn;kò sí èémí ninu wọn.

15. Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n;ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni.

16. Ìpín Jakọbu kò rí bí àwọn wọnyi,nítorí òun ló dá ohun gbogbo,Israẹli sì ni ẹ̀yà tí ó yàn, gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.

17. Ẹ gbé ẹrù yín nílẹ̀,ẹ̀yin tí ọ̀tá dótì wọnyi!

18. Nítorí OLUWA wí pé,“Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò.N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn,kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.”

19. Mo gbé, nítorí mo fara gbọgbẹ́!Ọgbẹ́ náà sì pọ̀.Ṣugbọn mo sọ fún ara mi pé,“Ìyà gan-an ni èyí jẹ́ fún mi,mo sì gbọdọ̀ fara dà á.”

Ka pipe ipin Jeremaya 10