Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 7:21-24 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n kú patapata, ati ẹyẹ, ati ẹran ọ̀sìn, ati ẹranko, ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà ati eniyan.

22. Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń mí lórí ilẹ̀ ayé patapata ni wọ́n kú.

23. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe pa gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé run: gbogbo eniyan, gbogbo ẹranko, gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati ẹyẹ. Noa nìkan ni kò kú ati àwọn tí wọ́n jọ wà ninu ọkọ̀ pẹlu rẹ̀.

24. Aadọjọ (150) ọjọ́ gbáko ni omi fi bo gbogbo ilẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 7