Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 7:10-16 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi bo ilẹ̀ ayé.

11. Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keji ọdún tí Noa di ẹni ẹgbẹta (600) ọdún, ni orísun alagbalúgbú omi tí ó wà ninu ọ̀gbun ńlá lábẹ́ ilẹ̀ ya, tí gbogbo fèrèsé omi tí ó wà ní ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀,

12. òjò sì rọ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru.

13. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti ati aya rẹ̀ ati àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta;

14. pẹlu àwọn ẹranko ati àwọn ẹran ọ̀sìn, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati oniruuru àwọn ẹyẹ.

15. Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè patapata ni wọ́n wọ inú ọkọ̀ tọ Noa lọ ní meji meji.

16. Gbogbo àwọn ohun ẹlẹ́mìí, akọ kan, abo kan, ní oríṣìí kọ̀ọ̀kan wọlé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Noa. OLUWA bá ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ náà.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 7