orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 5 BIBELI MIMỌ (BM)

Ìwé Àkọsílẹ̀ Ìran Adamu

1. Àkọsílẹ̀ ìran Adamu nìyí: Nígbà tí Ọlọrun dá eniyan, ó dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀.

2. Takọ-tabo ni ó dá wọn, ó súre fún wọn, ó sì sọ wọ́n ní eniyan.

3. Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti.

4. Lẹ́yìn tí ó bí Seti, ó tún gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

5. Gbogbo ọdún tí Adamu gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), kí ó tó kú.

6. Nígbà tí Seti di ẹni ọdún marundinlaadọfa (105), ó bí Enọṣi.

7. Lẹ́yìn tí ó bí Enọṣi, ó tún gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé meje (807) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

8. Gbogbo ọdún tí Seti gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejila (912), kí ó tó kú.

9. Nígbà tí Enọṣi di ẹni aadọrun-un ọdún, ó bí Kenani.

10. Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé mẹẹdogun (815) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

11. Gbogbo ọdún tí Enọṣi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé marun-un (905) kí ó tó kú.

12. Nígbà tí Kenani di ẹni aadọrin ọdún, ó bí Mahalaleli.

13. Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ogoji (840) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

14. Gbogbo ọdún tí Kenani gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mẹ́wàá (910) kí ó tó kú.

15. Nígbà tí Mahalaleli di ẹni ọdún marundinlaadọrin, ó bí Jaredi.

16. Lẹ́yìn tí ó bí Jaredi, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

17. Gbogbo ọdún tí Mahalaleli gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó dín marun-un (895) kí ó tó kú.

18. Nígbà tí Jaredi di ẹni ọdún mejilelọgọjọ (162) ó bí Enọku.

19. Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

20. Gbogbo ọdún tí Jaredi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejilelọgọta (962) kí ó tó kú.

21. Nígbà tí Enọku di ẹni ọdún marundinlaadọrin ó bí Metusela.

22. Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

23. Gbogbo ọdún tí Enọku gbé láyé jẹ́ ọọdunrun ọdún ó lé marundinlaadọrin (365).

24. Enọku wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, nígbà tí ó yá, wọn kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun mú un lọ.

25. Nígbà tí Metusela di ẹni ọgọsan-an ọdún ó lé meje (187) ó bí Lamẹki.

26. Lẹ́yìn tí ó bí Lamẹki, ó gbé ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mejilelọgọrin (782) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

27. Gbogbo ọdún tí Metusela gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mọkandinlaadọrin (969) kí ó tó kú.

28. Nígbà tí Lamẹki di ẹni ọdún mejilelọgọsan-an (182), ó bí ọmọkunrin kan.

29. Ó sọ ọ́ ní Noa, ó ní: “Eléyìí ni yóo mú ìtura wá fún wa ninu iṣẹ́ ati wahala wa tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi gégùn-ún.”

30. Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

31. Gbogbo ọdún tí Lamẹki gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mẹtadinlọgọrin (777) kí ó tó kú.

32. Nígbà tí Noa di ẹni ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún, ó bí Ṣemu, Hamu ati Jafẹti.