Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 49:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin,ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn.

6. Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀,ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́.Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan,wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá.

7. Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le,ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n.N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu,n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli.

8. Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́,apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ;àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ.

9. Juda dàbí kinniun,tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán,a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀.Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ,kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ.

10. Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda,arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba,títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín;gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

11. Yóo máa so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà,yóo so àwọ́nsìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà dáradára,bẹ́ẹ̀ ni oje àjàrà ni yóo máa fi fọ ẹ̀wù rẹ̀.

12. Ojú rẹ̀ yóo pọ́n fún àmutẹ́rùn ọtí waini,eyín rẹ̀ yóo sì funfun fún àmutẹ́rùn omi wàrà.

13. “Sebuluni yóo máa gbé etí òkun,ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye,Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀.

14. “Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbáratí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 49