Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 49:20-31 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀,oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde.

21. Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri,tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà.

22. Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri.

23. Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan,wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi,

24. sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì,apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i.Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun,(ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà,tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli),

25. Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́.Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá,yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀,ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn.

26. Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ,kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu,ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀.

27. “Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa,a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀,ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.”

28. Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un.

29. Jakọbu kìlọ̀ fún wọn, ó ní, “Mo ṣetán, mò ń re ibi àgbà á rè, inú ibojì tí wọ́n sin àwọn baba mi sí, ninu ihò òkúta tí ó wà ninu ilẹ̀ Efuroni, ará Hiti, ni kí ẹ sin mí sí.

30. Ihò òkúta yìí wà ninu pápá ní Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure ní ilẹ̀ Kenaani. Lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti ni Abrahamu ti rà á pọ̀ mọ́ ilẹ̀ náà, kí ó lè rí ibi fi ṣe itẹ́ òkú.

31. Níbẹ̀ ni wọ́n sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni wọ́n sin Isaaki sí ati Rebeka aya rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi náà sì sin Lea sí.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 49