Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 49:14-28 BIBELI MIMỌ (BM)

14. “Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbáratí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀.

15. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé ibi ìsinmi dáraati pé ilẹ̀ náà dára,ó tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ láti ru ẹrù,ó sì di ẹni tí wọn ń mú sìn bí ẹrú.

16. Dani ni yóo máa ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli.

17. Dani yóo dàbí ejò lójú ọ̀nà,ati bíi paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,tí ń bu ẹṣin ní gìgísẹ̀ jẹ,kí ẹni tí ó gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn.

18. Mo dúró de ìgbàlà rẹ, Oluwa.

19. Àwọn olè yóo máa kó Gadi lẹ́rù,ṣugbọn bí wọ́n ti ń kó o,bẹ́ẹ̀ ni yóo sì máa gbà á pada.

20. Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀,oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde.

21. Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri,tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà.

22. Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri.

23. Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan,wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi,

24. sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì,apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i.Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun,(ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà,tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli),

25. Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́.Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá,yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀,ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn.

26. Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ,kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu,ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀.

27. “Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa,a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀,ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.”

28. Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 49