Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 49:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jakọbu ranṣẹ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ kó ara yín jọ kí n lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ iwájú fún yín.

2. Ẹ péjọ kí ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ Israẹli, baba yín.

3. Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi,ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ,tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi.

4. Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn,o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀,o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́.

5. Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin,ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn.

6. Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀,ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́.Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan,wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá.

7. Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le,ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n.N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu,n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli.

8. Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́,apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ;àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ.

9. Juda dàbí kinniun,tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán,a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀.Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ,kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 49