Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 46:8-24 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀,

9. ati àwọn ọmọ Reubẹni wọnyi: Hanoku, Palu, Hesironi, ati Karimi.

10. Àwọn ọmọ ti Simeoni ni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari, ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani bí fún un.

11. Àwọn ọmọ ti Lefi ni: Geriṣoni, Kohati, ati Merari.

12. Àwọn ọmọ ti Juda ni: Eri, Onani, Ṣela, Peresi, ati Sera, (ṣugbọn, Eri ati Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani) àwọn ọmọ ti Peresi ni Hesironi ati Hamuli.

13. Àwọn ọmọ ti Isakari ni: Tola, Pua, Jobu ati Ṣimironi.

14. Àwọn ọmọ ti Sebuluni ni: Seredi, Eloni, ati Jaleeli.

15. (Àwọn ni ọmọ tí Lea bí fún Jakọbu ní Padani-aramu ati Dina, ọmọ rẹ̀ obinrin.) Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin jẹ́ mẹtalelọgbọn.

16. Àwọn ọmọ ti Gadi ni: Sifioni, Hagi, Ṣuni, Esiboni, Eri, Arodu, ati Areli.

17. Àwọn ọmọ ti Aṣeri ni: Imina, Iṣifa, Iṣifi, Beraya, ati Sera arabinrin wọn. Àwọn ọmọ ti Beraya ni Heberi, ati Malikieli.

18. (Àwọn ni ọmọ tí Silipa bí fún Jakọbu. Silipa ni iranṣẹ tí Labani fún Lea ọmọ rẹ̀ obinrin, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlogun.)

19. Àwọn ọmọ ti Rakẹli ni Josẹfu ati Bẹnjamini.

20. Asenati, ọmọbinrin Pọtifera bí Manase ati Efuraimu fún Josẹfu ní ilẹ̀ Ijipti. Pọtifera ni babalóòṣà oriṣa Oni, ní Ijipti.

21. Àwọn ọmọ ti Bẹnjamini ni: Bela, Bekeri, Aṣibeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Hupimu, ati Aridi,

22. (àwọn wọnyi ni ọmọ tí Rakẹli bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹrinla).

23. Ọmọ ti Dani ni Huṣimu.

24. Àwọn ọmọ ti Nafutali ni Jaseeli, Guni, Jeseri, ati Ṣilemu.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 46