Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 46:29-34 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Josẹfu bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó lọ pàdé Israẹli, baba rẹ̀ ní Goṣeni. Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́.

30. Israẹli bá wí fún Josẹfu, ó ní, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ojú kàn ọ́ báyìí, tí mo sì rí i pé o wà láàyè, bí ikú bá tilẹ̀ wá dé, ó yá mi.”

31. Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo ìdílé baba rẹ̀ pé òun óo lọ sọ fún Farao pé àwọn arakunrin òun ati ìdílé baba òun tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Kenaani ti dé sọ́dọ̀ òun.

32. Ati pé darandaran ni wọ́n, ìtọ́jú ẹran ọ̀sìn ni iṣẹ́ wọn, wọ́n sì kó gbogbo agbo mààlúù ati agbo ewúrẹ́, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní lọ́wọ́ wá.

33. Ó ní nígbà tí Farao bá pè wọ́n, tí ó bá bi wọ́n léèrè pé irú iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe,

34. kí wọ́n dá a lóhùn pé, ẹran ọ̀sìn ni àwọn ti ń tọ́jú láti ìgbà èwe àwọn títí di ìsinsìnyìí, ati àwọn ati àwọn baba àwọn, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé ìríra patapata ni gbogbo darandaran jẹ́ fún àwọn ará Ijipti.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 46