Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 46:17-28 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Àwọn ọmọ ti Aṣeri ni: Imina, Iṣifa, Iṣifi, Beraya, ati Sera arabinrin wọn. Àwọn ọmọ ti Beraya ni Heberi, ati Malikieli.

18. (Àwọn ni ọmọ tí Silipa bí fún Jakọbu. Silipa ni iranṣẹ tí Labani fún Lea ọmọ rẹ̀ obinrin, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlogun.)

19. Àwọn ọmọ ti Rakẹli ni Josẹfu ati Bẹnjamini.

20. Asenati, ọmọbinrin Pọtifera bí Manase ati Efuraimu fún Josẹfu ní ilẹ̀ Ijipti. Pọtifera ni babalóòṣà oriṣa Oni, ní Ijipti.

21. Àwọn ọmọ ti Bẹnjamini ni: Bela, Bekeri, Aṣibeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Hupimu, ati Aridi,

22. (àwọn wọnyi ni ọmọ tí Rakẹli bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹrinla).

23. Ọmọ ti Dani ni Huṣimu.

24. Àwọn ọmọ ti Nafutali ni Jaseeli, Guni, Jeseri, ati Ṣilemu.

25. (Àwọn ọmọ tí Biliha bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ meje), Biliha ni iranṣẹbinrin tí Labani fún Rakẹli, ọmọ rẹ̀ obinrin.

26. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ijipti, tí wọ́n jẹ́ ọmọ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlaadọrin, láìka àwọn iyawo àwọn ọmọ rẹ̀.

27. Àwọn ọmọ tí Josẹfu bí ní Ijipti jẹ́ meji. Gbogbo eniyan tí ó ti ìdílé Jakọbu jáde lọ sí Ijipti patapata wá jẹ́ aadọrin.

28. Jakọbu rán Juda ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Josẹfu pé kí Josẹfu wá pàdé òun ní Goṣeni, wọ́n sì wá sí ilẹ̀ Goṣeni.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 46