Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 45:26-28 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Wọ́n sọ fún un pé, “Josẹfu kò kú, ó wà láàyè, ati pé òun ni alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, orí rẹ̀ fò lọ fee, kò kọ́ gbà wọ́n gbọ́.

27. Ṣugbọn nígbà tí ó gbọ́ gbogbo ohun tí Josẹfu wí fún wọn, tí ó tún rí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin tí Josẹfu fi ranṣẹ pé kí wọ́n fi gbé òun wá, ara rẹ̀ wálẹ̀.

28. Israẹli bá dáhùn, ó ní, “Josẹfu, ọmọ mi wà láàyè! Ó ti parí, n óo lọ fi ojú kàn án kí n tó kú.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 45