Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 45:12-25 BIBELI MIMỌ (BM)

12. “Ẹ̀yin pàápàá fi ojú rí i, Bẹnjamini arakunrin mi náà sì rí i pẹlu pé èmi gan-an ni mò ń ba yín sọ̀rọ̀.

13. Ẹ níláti sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Ijipti, ati gbogbo ohun tí ẹ ti rí. Ẹ tètè yára mú baba mi wá bá mi níhìn-ín.”

14. Ó bá rọ̀ mọ́ Bẹnjamini arakunrin rẹ̀ lọ́rùn, ó sì bú sẹ́kún, bí Bẹnjamini náà ti rọ̀ mọ́ ọn, ni òun náà bú sẹ́kún.

15. Josẹfu bá fi ẹnu ko àwọn arakunrin rẹ̀ lẹ́nu lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì sọkún, lẹ́yìn náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀.

16. Nígbà tí gbogbo ìdílé Farao gbọ́ pé àwọn arakunrin Josẹfu dé, inú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ dùn pupọ.

17. Farao sọ fún Josẹfu pé kí ó sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ kí wọ́n múra, kí wọ́n di ẹrù ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, kí wọ́n tètè pada lọ sí Kenaani,

18. kí wọ́n sì lọ mú baba rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ wá sọ́dọ̀ òun. Ó ní òun óo fún un ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, wọn yóo sì jẹ àjẹyó ninu ilẹ̀ náà.

19. Ó ní kí Josẹfu pàṣẹ fún wọn pẹlu kí wọ́n kó kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi kó àwọn ọmọde ati àwọn obinrin, kí baba wọn náà sì máa bá wọn bọ̀.

20. Ó ní kí wọ́n má ronú àwọn dúkìá wọn nítorí àwọn ni wọn yóo ni ilẹ̀ tí ó dára jù ní Ijipti.

21. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí ọba ti wí, Josẹfu fún wọn ní kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Farao, ó sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo máa jẹ lọ́nà.

22. Ó fún olukuluku wọn ní ìpààrọ̀ aṣọ kọ̀ọ̀kan, ṣugbọn ó fún Bẹnjamini ní ọọdunrun (300) ṣekeli fadaka ati ìpààrọ̀ aṣọ marun-un.

23. Ó di àwọn nǹkan dáradára ilẹ̀ Ijipti ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó di ọkà ati oúnjẹ ru abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó kó wọn ranṣẹ sí baba rẹ̀ pé kí ó rí ohun máa jẹ bọ̀ lọ́nà.

24. Ó bá ní kí àwọn arakunrin òun máa lọ, bí wọ́n sì ti fẹ́ máa lọ, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má bá ara wọn jà lọ́nà.

25. Wọ́n bá kúrò ní Ijipti, wọ́n pada sọ́dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 45