Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 44:23-34 BIBELI MIMỌ (BM)

23. O bá sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé bí àbíkẹ́yìn wa patapata kò bá bá wa wá, a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ mọ́.

24. “Nígbà tí a pada dé ọ̀dọ̀ baba wa, iranṣẹ rẹ, a rò fún un bí o ti wí.

25. Nígbà tí ó ní kí á tún lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá,

26. a wí fún un pé, a kò ní lọ, àfi bí arakunrin wa bá tẹ̀lé wa, nítorí pé a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ bí kò bá bá wa wá.

27. Baba wa sọ fún wa pé a mọ̀ pé ọkunrin meji ni Rakẹli, aya òun bí fún òun,

28. ọ̀kan fi òun sílẹ̀, òun sì wí pé, dájúdájú, ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, òun kò sì tíì fi ojú òun kàn án láti ìgbà náà.

29. Ó ní bí a bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ òun, bí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀ sí i, pẹlu arúgbó ara òun yìí, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo pa òun.

30. “Nítorí náà, bí mo bá pada dé ọ̀dọ̀ baba mi tí n kò sì mú ọmọdekunrin náà lọ́wọ́, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ọmọdekunrin yìí gan-an ni ó fi ẹ̀mí tẹ̀,

31. bí kò bá rí i pẹlu wa, kíkú ni yóo kú. Yóo sì wá jẹ́ pé àwa ni a fa ìbànújẹ́ fún baba wa, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ìbànújẹ́ yìí ni yóo sì pa á.

32. Èmi ni mo dúró fún ọmọdekunrin náà lọ́dọ̀ baba wa, mo wí fún un pé, ‘Bí n kò bá mú ọmọ yìí pada, ẹ̀bi rẹ̀ yóo wà lórí mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.’

33. Nígbà tí ọ̀rọ̀ wá rí bí ó ti rí yìí, oluwa mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi di ẹrú rẹ dípò ọmọdekunrin yìí, jẹ́ kí òun máa bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pada lọ.

34. Báwo ni n óo ṣe pada dé iwájú baba mi láìmú ọmọ náà lọ́wọ́? Ẹ̀rù ohun burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí baba mi, ń bà mí.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 44