Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 41:46-53 BIBELI MIMỌ (BM)

46. Josẹfu jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lábẹ́ Farao, ọba Ijipti. A máa lọ láti ààfin ọba Farao káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

47. Láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà, ilẹ̀ so èso lọpọlọpọ.

48. Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà.

49. Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe kó ọkà jọ jantirẹrẹ bíi yanrìn etí òkun. Nígbà tó yá, òun gan-an kò mọ ìwọ̀n ọkà náà mọ́, nítorí pé ó ti pọ̀ kọjá wíwọ̀n.

50. Asenati, ọmọ Pọtifera, babalóòṣà Oni, bí ọkunrin meji fún Josẹfu kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀.

51. Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.”

52. Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.”

53. Nígbà tí ó yá, ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà ní Ijipti dópin.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 41