Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 41:32-44 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ.

33. “Bí ọ̀rọ̀ ti rí yìí, ó yẹ kí kabiyesi yan ọkunrin kan tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye, kí ó fi ṣe olórí ní ilẹ̀ Ijipti.

34. Kí kabiyesi yan àwọn alabojuto ní ilẹ̀ náà kí wọ́n kó ìdámárùn-ún ìkórè ilẹ̀ Ijipti jọ láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóo fi wà.

35. Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ wọnyi jọ ninu ọdún tí oúnjẹ yóo pọ̀, kí wọ́n sì kó wọn pamọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá, pẹlu àṣẹ kabiyesi, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ọ.

36. Oúnjẹ yìí ni àwọn eniyan yóo máa jẹ láàrin ọdún meje tí ìyàn yóo mú ní ilẹ̀ Ijipti, kí ilẹ̀ náà má baà parun ní àkókò ìyàn náà.”

37. Ìmọ̀ràn náà dára lójú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀.

38. Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?”

39. Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọrun fi gbogbo nǹkan yìí hàn, kò sí ẹni tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye bíi rẹ.

40. Ìwọ ni yóo máa ṣe olórí ilé mi, gbogbo àṣẹ tí o bá sì pa ni àwọn eniyan mi yóo tẹ̀lé, kìkì pé mo jẹ́ ọba nìkan ni n óo fi jù ọ́ lọ.”

41. Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó! Mo fi ọ́ ṣe alákòóso ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.”

42. Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn.

43. Farao ní kí Josẹfu gun ọkọ̀ ogun rẹ̀ keji gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà!” Bẹ́ẹ̀ ni Farao ṣe fi Josẹfu ṣe olórí, ní ilẹ̀ Ijipti.

44. Farao tún sọ fún un pé, “Èmi ni Farao, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Ijipti láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 41