Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 41:26-35 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Àwọn mààlúù rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ meje nnì ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí wọ́n yọmọ dúró fún ọdún meje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá mejeeji.

27. Àwọn mààlúù meje tí wọ́n rù, tí wọ́n sì rí jàpàlà jàpàlà tí wọ́n jáde lẹ́yìn àwọn ti àkọ́kọ́, ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí kò yọmọ, tí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ lára, àwọn náà dúró fún ìyàn ọdún meje.

28. Bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an ni mo sọ fún kabiyesi yìí, Ọlọrun ti fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi.

29. Ọdún meje kan ń bọ̀ tí oúnjẹ yóo pọ̀ yanturu ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti,

30. ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí.

31. Ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀ pé oúnjẹ ti fi ìgbà kan pọ̀ rí, nítorí ìyàn ńlá tí yóo tẹ̀lé e yóo burú jáì.

32. Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ.

33. “Bí ọ̀rọ̀ ti rí yìí, ó yẹ kí kabiyesi yan ọkunrin kan tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye, kí ó fi ṣe olórí ní ilẹ̀ Ijipti.

34. Kí kabiyesi yan àwọn alabojuto ní ilẹ̀ náà kí wọ́n kó ìdámárùn-ún ìkórè ilẹ̀ Ijipti jọ láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóo fi wà.

35. Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ wọnyi jọ ninu ọdún tí oúnjẹ yóo pọ̀, kí wọ́n sì kó wọn pamọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá, pẹlu àṣẹ kabiyesi, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ọ.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 41