Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 40:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Agbọ́tí bá rọ́ àlá tirẹ̀ fún Josẹfu, ó ní, “Mo rí ìtàkùn àjàrà kan lójú àlá.

10. Ìtàkùn náà ní ẹ̀ka mẹta, bí ewé rẹ̀ ti yọ, lẹsẹkẹsẹ, ni ó tanná, ó so, èso rẹ̀ sì pọ́n.

11. Ife Farao wà ní ọwọ́ mi, mo bá mú èso àjàrà náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí fún un sinu ife Farao, mo sì gbé ife náà lé Farao lọ́wọ́.”

12. Josẹfu bá sọ fún un pé, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn ẹ̀ka mẹta tí o rí dúró fún ọjọ́ mẹta.

13. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Farao yóo yọ ọ́ jáde, yóo dáríjì ọ́, yóo sì fi ọ́ sí ipò rẹ pada, o óo sì tún máa gbé ọtí fún Farao bíi ti àtẹ̀yìnwá.

14. Ṣugbọn ṣá o, ranti mi nígbà tí ó bá dára fún ọ, jọ̀wọ́, ṣe mí lóore kan, ròyìn mi fún Farao, kí Farao sì yọ mí kúrò ninu àhámọ́ yìí.

15. Nítorí pé jíjí ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ Heberu, ati pé níhìn-ín gan-an, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ tí wọ́n fi gbé mi jù sẹ́wọ̀n yìí.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 40