Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 4:3-19 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nígbà tí ó yá, Kaini mú ninu èso oko rẹ̀, ó fi rúbọ sí OLUWA.

4. Abeli náà mú àkọ́bí ọ̀kan ninu àwọn aguntan rẹ̀, ó pa á, ó sì fi ibi tí ó lọ́ràá, tí ó dára jùlọ lára rẹ̀ rúbọ sí OLUWA. Inú OLUWA dùn sí Abeli, ó sì gba ẹbọ rẹ̀,

5. ṣugbọn inú Ọlọrun kò dùn sí Kaini, kò sì gba ẹbọ rẹ̀. Inú bí Kaini, ó sì fa ojú ro.

6. OLUWA bá bi Kaini, ó ní, “Kí ló dé tí ò ń bínú, tí o sì fa ojú ro?

7. Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.”

8. Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa.

9. OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”

10. OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí.

11. Wò ó! mo fi ọ́ gégùn-ún lórí ilẹ̀ tí ó mu ẹ̀jẹ̀ arakunrin rẹ tí o pa.

12. Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.”

13. Kaini dá OLUWA lóhùn, ó ní, “Ìjìyà yìí ti pọ̀jù fún mi.

14. O lé mi kúrò lórí ilẹ̀, ati kúrò níwájú rẹ, n óo sì di ìsáǹsá ati alárìnká lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí ó bá yá, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi ni yóo pa mí.”

15. Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á.

16. Kaini bá kúrò níwájú OLUWA, ó lọ ń gbé ìlú tí ń jẹ́ Nodu. Ó wà ní apá ìlà oòrùn ọgbà Edẹni.

17. Kaini bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí Enọku. Kaini lọ tẹ ìlú kan dó, ó sọ ìlú náà ní Enọku, tí í ṣe orúkọ ọmọ rẹ̀.

18. Enọku bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Iradi. Iradi bí Mehujaeli, Mehujaeli bí Metuṣaeli, Metuṣaeli bí Lamẹki.

19. Lamẹki fẹ́ iyawo meji, ọ̀kan ń jẹ́ Ada, ekeji ń jẹ́ Sila.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 4