Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 36:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí ó ṣe, Esau kó àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn mààlúù rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ti kójọ ní ilẹ̀ Kenaani, ó kó kúrò ní ilẹ̀ Kenaani lọ́dọ̀ Jakọbu, arakunrin rẹ̀.

7. Ìdí ni pé ọrọ̀ wọn ti pọ̀ ju kí wọ́n jọ máa gbé pọ̀ lọ, ilẹ̀ tí wọ́n sì ti ń ṣe àtìpó kò gbà wọ́n mọ́, nítorí pé wọ́n ní ẹran ọ̀sìn tí ó pọ̀.

8. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe di ẹni tí ń gbé orí òkè Seiri. Esau kan náà ni ń jẹ́ Edomu.

9. Àkọsílẹ̀ ìran Esau, baba àwọn ará Edomu, tí ń gbé orí òkè Seiri nìyí:

10. orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ ni, Elifasi, tí Ada bí, ati Reueli, tí Basemati bí.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 36