Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 36:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àkọsílẹ̀ ìran Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu nìyí:

2. Ninu àwọn ọmọbinrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ aya, ekinni ń jẹ́ Ada, ọmọ Eloni ará Hiti, ekeji ń jẹ́ Oholibama, ọmọ Ana tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Sibeoni, ará Hifi.

3. Ẹkẹta ń jẹ́ Basemati ọmọ Iṣimaeli, arabinrin Nebaiotu.

4. Ada bí Elifasi fún Esau, Basemati bí Reueli.

5. Oholibama bí Jeuṣi, Jalamu ati Kora. Àwọn ni ọmọ Esau, tí àwọn aya rẹ̀ bí fún un ní ilẹ̀ Kenaani.

6. Nígbà tí ó ṣe, Esau kó àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn mààlúù rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ti kójọ ní ilẹ̀ Kenaani, ó kó kúrò ní ilẹ̀ Kenaani lọ́dọ̀ Jakọbu, arakunrin rẹ̀.

7. Ìdí ni pé ọrọ̀ wọn ti pọ̀ ju kí wọ́n jọ máa gbé pọ̀ lọ, ilẹ̀ tí wọ́n sì ti ń ṣe àtìpó kò gbà wọ́n mọ́, nítorí pé wọ́n ní ẹran ọ̀sìn tí ó pọ̀.

8. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe di ẹni tí ń gbé orí òkè Seiri. Esau kan náà ni ń jẹ́ Edomu.

9. Àkọsílẹ̀ ìran Esau, baba àwọn ará Edomu, tí ń gbé orí òkè Seiri nìyí:

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 36