Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 35:21-29 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Jakọbu tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó pàgọ́ rẹ̀ sí òdìkejì ilé ìṣọ́ Ederi.

22. Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.

23. Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni.

24. Àwọn tí Rakẹli bí ni: Josẹfu ati Bẹnjamini.

25. Àwọn tí Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli bí ni: Dani ati Nafutali.

26. Àwọn tí Silipa, iranṣẹbinrin Lea bí ni: Gadi ati Aṣeri. Àwọn wọnyi ni àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún Jakọbu ní Padani-aramu.

27. Jakọbu pada sọ́dọ̀ Isaaki, baba rẹ̀, ní Mamure, ìlú yìí kan náà ni wọ́n ń pè ní Kiriati Ariba tabi Heburoni, níbi tí Abrahamu ati Isaaki gbé.

28. Isaaki jẹ́ ẹni ọgọsan-an (180) ọdún nígbà tí ó kú.

29. Ó dàgbà, ó darúgbó lọpọlọpọ kí ó tó kú. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Esau ati Jakọbu, sì sin ín.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 35