Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 34:23-26 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ṣebí gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo ohun ìní wọn ni yóo di tiwa? Ẹ ṣá jẹ́ kí á gbà fún wọn, wọn yóo sì máa bá wa gbé.”

24. Gbogbo àwọn ará ìlú náà gba ohun tí Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wí, gbogbo ọkunrin sì kọlà abẹ́.

25. Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ará kan wọ́n, meji ninu àwọn ọmọ Jakọbu, Simeoni ati Lefi, arakunrin Dina, mú idà wọn, wọ́n jálu àwọn ará ìlú náà lójijì, wọ́n sì pa gbogbo ọkunrin wọn.

26. Wọ́n fi idà pa Hamori pẹlu, ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Wọ́n mú Dina jáde kúrò ní ilé Ṣekemu, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 34