Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 34:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.

15. Ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣeéṣe ni pé kí ẹ̀yin náà dàbí wa, kí gbogbo ọkunrin yín kọlà abẹ́.

16. Nígbà náà ni a óo tó máa fi ọmọ wa fun yín tí àwa náà yóo máa fẹ́ ọmọ yín, a óo máa gbé pọ̀ pẹlu yín, a óo sì di ọ̀kan.

17. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbà láti kọlà abẹ́, a óo mú ọmọbinrin wa, a óo sì máa lọ.”

18. Ọ̀rọ̀ wọn dùn mọ́ Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ ninu.

19. Ọdọmọkunrin náà kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, nítorí pé ó fẹ́ràn ọmọbinrin Jakọbu lọpọlọpọ. Ninu gbogbo ìdílé ọmọkunrin yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ.

20. Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ bá lọ sí ẹnubodè ìlú, wọ́n sọ fún àwọn ọkunrin ìlú náà pé,

21. “Ìbágbé àwọn eniyan wọnyi tuni lára pupọ, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ wa, kí wọ́n máa tà, kí wọ́n máa rà, ilẹ̀ yìí tóbi tó, ó gbà wọ́n. Ẹ jẹ́ kí á máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, kí àwọn náà sì máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wa.

22. Ohun kan ṣoṣo ni wọ́n ní kí á ṣe kí á lè jọ máa gbé pọ̀, kí á sì di ọ̀kan, wọ́n ní olukuluku ọkunrin wa gbọdọ̀ kọlà abẹ́ gẹ́gẹ́ bíi tiwọn.

23. Ṣebí gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo ohun ìní wọn ni yóo di tiwa? Ẹ ṣá jẹ́ kí á gbà fún wọn, wọn yóo sì máa bá wa gbé.”

24. Gbogbo àwọn ará ìlú náà gba ohun tí Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wí, gbogbo ọkunrin sì kọlà abẹ́.

25. Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ará kan wọ́n, meji ninu àwọn ọmọ Jakọbu, Simeoni ati Lefi, arakunrin Dina, mú idà wọn, wọ́n jálu àwọn ará ìlú náà lójijì, wọ́n sì pa gbogbo ọkunrin wọn.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 34