Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 33:6-12 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn bá súnmọ́ wọn, wọ́n sì wólẹ̀ fún Esau.

7. Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ náà súnmọ́ wọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un, lẹ́yìn náà ni Josẹfu ati Rakẹli súnmọ́ ọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un bákan náà.

8. Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.”

9. Ṣugbọn Esau dáhùn pé, “Èyí tí mo ní ti tó mi, arakunrin mi, máa fi tìrẹ sọ́wọ́.”

10. Ṣugbọn Jakọbu dáhùn pé, “Rárá o, jọ̀wọ́, bí mo bá bá ojurere rẹ pàdé nítòótọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá lọ́wọ́ mi, nítorí pé rírí tí mo rí ojú rẹ tí inú rẹ sì yọ́ sí mi tó báyìí, ó dàbí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọrun.

11. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ nítorí pé Ọlọrun ti ṣe oore fún mi lọpọlọpọ ati pé mo ní ànító.” Jakọbu rọ̀ ọ́ títí tí ó fi gbà á.

12. Lẹ́yìn náà, Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jẹ́ kí á múra kí á máa lọ n óo sì ṣáájú.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 33