Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 32:24-32 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Ó wá ku Jakọbu nìkan, ọkunrin kan bá a wọ ìjàkadì títí di àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ keji.

25. Nígbà tí ọkunrin náà rí i pé òun kò lè dá Jakọbu, ó fi ọwọ́ kan kòtò itan rẹ̀, eegun itan Jakọbu bá yẹ̀ níbi tí ó ti ń bá a jìjàkadì.

26. Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí n lọ nítorí ilẹ̀ ti ń mọ́” Ṣugbọn Jakọbu kọ̀, ó ní, “N kò ní jẹ́ kí o lọ, àfi bí o bá súre fún mi.”

27. Ọkunrin náà bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Jakọbu dáhùn pé, “Jakọbu ni.”

28. Ọkunrin náà bá dáhùn pé, “A kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni a óo máa pè ọ́, nítorí pé o ti bá Ọlọrun ati eniyan wọ ìjàkadì, o sì ti ṣẹgun.”

29. Jakọbu bá bẹ̀ ẹ́, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣugbọn ó dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí o fi ń bèèrè orúkọ mi?” Ó bá súre fún Jakọbu níbẹ̀.

30. Nítorí náà ni Jakọbu fi sọ ibẹ̀ ní Penieli, ó ní, “Mo ti rí Ọlọrun lojukooju, sibẹ mo ṣì wà láàyè.”

31. Oòrùn yọ kí ó tó kọjá Penueli, nítorí pé títiro ni ó ń tiro lọ nítorí itan rẹ̀.

32. Nítorí náà, títí di òní, àwọn ọmọ Israẹli kì í jẹ iṣan tí ó bo ihò itan níbi tí itan ti sopọ̀ mọ́ ìbàdí, nítorí pé ihò itan Jakọbu ni ọkunrin náà fọwọ́ kàn, orí iṣan tí ó so ó pọ̀ mọ́ ìbàdí.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 32