Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 3:21-24 BIBELI MIMỌ (BM)

21. OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.

22. Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.”

23. Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde.

24. Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 3