Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 3:17-23 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ó sọ fún Adamu, pé,“Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ,o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ,mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ.Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

18. Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ,ewéko ni o óo sì máa jẹ.

19. Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ,títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀,nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá.Erùpẹ̀ ni ọ́,o óo sì pada di erùpẹ̀.”

20. Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan.

21. OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.

22. Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.”

23. Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 3