Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 3:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”

11. Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”

12. Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

13. OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.”

14. OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

15. N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà,ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀.Wọn óo máa fọ́ ọ lórí,ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”

16. Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé,“N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún,ninu ìrora ni o óo máa bímọ.Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí,òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.”

17. Ó sọ fún Adamu, pé,“Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ,o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ,mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ.Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

18. Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ,ewéko ni o óo sì máa jẹ.

19. Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ,títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀,nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá.Erùpẹ̀ ni ọ́,o óo sì pada di erùpẹ̀.”

20. Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan.

21. OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 3