Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 29:26-35 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Labani dáhùn, ó ní, “Ní ilẹ̀ tiwa níhìn-ín, àwa kì í fi àbúrò fọ́kọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n.

27. Fara balẹ̀ parí àwọn ètò ọ̀sẹ̀ igbeyawo ti eléyìí, n óo sì fún ọ ní ekeji náà, ṣugbọn o óo tún sìn mí ní ọdún meje sí i.”

28. Jakọbu gbà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ọ̀sẹ̀ igbeyawo Lea parí, lẹ́yìn náà Labani fa Rakẹli, ọmọ rẹ̀ fún un.

29. Labani fi Biliha, ẹrubinrin rẹ̀ fún Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un.

30. Jakọbu bá Rakẹli náà lòpọ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ju Lea lọ, ó sì sin Labani fún ọdún meje sí i.

31. Nígbà tí OLUWA rí i pé Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó fún Lea ní ọmọ bí, ṣugbọn Rakẹli yàgàn.

32. Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.”

33. Ó tún lóyún, ó tún bí ọkunrin, ó ní, “Nítorí pé OLUWA ti gbọ́ pé wọ́n kórìíra mi ni ó ṣe fún mi ní ọmọ yìí pẹlu.” Ó bá sọ ọ́ ní Simeoni.

34. Ó tún lóyún, ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Ọkọ mi gbọdọ̀ faramọ́ mi wàyí, nítorí pé ó di ọkunrin mẹta tí mo bí fún un”, nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Lefi.

35. Ó tún lóyún ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Wàyí o, n óo yin OLUWA,” ó bá sọ ọ́ ní Juda. Lẹ́yìn rẹ̀, kò bímọ mọ́.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 29