Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 29:17-34 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ojú Lea kò fi bẹ́ẹ̀ fanimọ́ra, ṣugbọn Rakẹli jẹ́ arẹwà, ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra.

18. Jakọbu nífẹ̀ẹ́ Rakẹli, nítorí náà, ó sọ fún Labani pé, “N óo sìn ọ́ ní ọdún meje nítorí Rakẹli, ọmọ rẹ kékeré.”

19. Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó tẹ́ mi lọ́rùn láti fún ọ ju kí n fún ẹni ẹlẹ́ni lọ. Máa bá mi ṣiṣẹ́.”

20. Jakọbu bá sin Labani fún ọdún meje nítorí Rakẹli, ó sì dàbí ọjọ́ mélòó kan lójú rẹ̀ nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí Rakẹli.

21. Nígbà tí ó yá, Jakọbu sọ fún Labani pé, “Fún mi ní aya mi, kí á lè ṣe igbeyawo, nítorí ọjọ́ ti pé.”

22. Labani bá pe gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀ jọ, ó se àsè ńlá fún wọn.

23. Ṣugbọn nígbà tí ó di àṣáálẹ́, Lea ni wọ́n mú wá fún Jakọbu dípò Rakẹli, Jakọbu sì bá a lòpọ̀.

24. Labani fi Silipa ẹrubinrin rẹ̀ fún Lea pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un.

25. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, Jakọbu rí i pé Lea ni wọ́n mú wá fún òun. Ó bi Labani, ó ní, “Irú kí ni o ṣe sí mi yìí? Ṣebí nítorí Rakẹli ni mo fi sìn ọ́? Èéṣe tí o tàn mí jẹ?”

26. Labani dáhùn, ó ní, “Ní ilẹ̀ tiwa níhìn-ín, àwa kì í fi àbúrò fọ́kọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n.

27. Fara balẹ̀ parí àwọn ètò ọ̀sẹ̀ igbeyawo ti eléyìí, n óo sì fún ọ ní ekeji náà, ṣugbọn o óo tún sìn mí ní ọdún meje sí i.”

28. Jakọbu gbà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ọ̀sẹ̀ igbeyawo Lea parí, lẹ́yìn náà Labani fa Rakẹli, ọmọ rẹ̀ fún un.

29. Labani fi Biliha, ẹrubinrin rẹ̀ fún Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un.

30. Jakọbu bá Rakẹli náà lòpọ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ju Lea lọ, ó sì sin Labani fún ọdún meje sí i.

31. Nígbà tí OLUWA rí i pé Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó fún Lea ní ọmọ bí, ṣugbọn Rakẹli yàgàn.

32. Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.”

33. Ó tún lóyún, ó tún bí ọkunrin, ó ní, “Nítorí pé OLUWA ti gbọ́ pé wọ́n kórìíra mi ni ó ṣe fún mi ní ọmọ yìí pẹlu.” Ó bá sọ ọ́ ní Simeoni.

34. Ó tún lóyún, ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Ọkọ mi gbọdọ̀ faramọ́ mi wàyí, nítorí pé ó di ọkunrin mẹta tí mo bí fún un”, nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Lefi.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 29