Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 27:17-27 BIBELI MIMỌ (BM)

17. ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀.

18. Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?”

19. Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.”

20. Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.”

21. Isaaki bá wí tìfura-tìfura pé, “Súnmọ́ mi, kí n fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni ọ́ lóòótọ́.”

22. Jakọbu bá súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀, baba rẹ̀ fọwọ́ pa á lára, ó wí pé, “Ọwọ́ Esau ni ọwọ́ yìí, ṣugbọn ohùn Jakọbu ni ohùn yìí.”

23. Kò sì dá Jakọbu mọ̀, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ní irun bíi ti Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bá súre fún un.

24. Ó bèèrè pé, “Ṣé ìwọ gan-an ni Esau, ọmọ mi?” Jakọbu bá dáhùn pé, “Èmi ni.”

25. Nígbà náà ni ó wí pé, “Gbé oúnjẹ náà súnmọ́ mi, kí n jẹ ninu ẹran tí ọmọ mi pa, kí n sì súre fún ọ.” Jakọbu bá gbé oúnjẹ náà súnmọ́ ọn, ó jẹ ẹ́, ó bu ọtí waini fún un, ó sì mu ún.

26. Isaaki baba rẹ̀ bá pè é ó ní, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.”

27. Jakọbu bá súnmọ́ baba rẹ̀, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Baba rẹ̀ gbóòórùn aṣọ rẹ̀, ó sì súre fún un, ó ní,“Òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí OLUWA ti bukun.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 27