Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 26:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Kí ó tó lọ sí Gerari, Ọlọrun farahàn án, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ lọ sí Ijipti, kí ó máa gbé ilẹ̀ tí òun sọ fún un.

3. Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ.

4. N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ wọnyi. Nípasẹ̀ wọn ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé,

5. nítorí pé Abrahamu gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo òfin ati ìlànà mi mọ́ patapata.”

6. Isaaki bá ń gbé Gerari.

7. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin.

8. Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí Isaaki ti ń gbé ìlú náà fún ìgbà pípẹ́, Abimeleki, ọba àwọn ará ìlú Filistia yọjú lójú fèrèsé ààfin rẹ̀, ó rí i tí Isaaki ati Rebeka ń tage.

9. Abimeleki bá pe Isaaki, ó wí pé, “Àṣé iyawo rẹ ni Rebeka! Kí ni ìdí tí o fi pè é ní arabinrin rẹ fún wa?” Isaaki bá dáhùn pé, “Mo rò pé wọ́n lè pa mí nítorí rẹ̀ ni.”

10. Abimeleki bá dá a lóhùn pé, “Irú kí ni o dánwò sí wa yìí? Ǹjẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi bá ti bá aya rẹ lòpọ̀ ńkọ́? O ò bá mú ẹ̀bi wá sórí wa.”

11. Nítorí náà Abimeleki kìlọ̀ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ọkunrin yìí tabi aya rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa á.”

12. Isaaki dá oko ní ilẹ̀ náà, láàrin ọdún kan ṣoṣo ó rí ìkórè ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un (100) ohun tí ó gbìn nítorí OLUWA bukun un.

13. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní àníkún títí ó fi di ọlọ́rọ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 26