Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 25:22-29 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA.

23. OLUWA wí fún un pé,“Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ,a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà,ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ,èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.”

24. Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́.

25. Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau.

26. Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn.

27. Nígbà tí àwọn ọmọ náà dàgbà, Esau di ògbójú ọdẹ, a sì máa lọ sí oko ọdẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ilé ni ó sì máa ń sábà gbé ní tirẹ̀.

28. Isaaki fẹ́ràn Esau nítorí ẹran ìgbẹ́ tí ó máa ń fún un jẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu ni Rebeka fẹ́ràn.

29. Ní ọjọ́ kan, bí Jakọbu ti ń se ẹ̀bẹ lọ́wọ́ ni Esau ti oko ọdẹ dé, ebi sì ti fẹ́rẹ̀ pa á kú.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 25