Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 21:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Sara bá pe Abrahamu, ó sọ fún un pé, “Lé ẹrubinrin yìí jáde pẹlu ọmọ rẹ̀, nítorí pé ọmọ ẹrubinrin yìí kò ní jẹ́ àrólé pẹlu Isaaki ọmọ mi.”

11. Ọ̀rọ̀ yìí kò dùn mọ́ Abrahamu ninu nítorí Iṣimaeli, ọmọ rẹ̀.

12. Ṣugbọn Ọlọrun wí fún Abrahamu pé, “Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọmọ yìí ati ti ẹrubinrin rẹ, ohunkohun tí Sara bá wí fún ọ ni kí o ṣe, nítorí pé orúkọ Isaaki ni wọn yóo fi máa pe atọmọdọmọ rẹ.

13. N óo sọ ọmọ ẹrubinrin náà di orílẹ̀ èdè ńlá pẹlu, nítorí ọmọ rẹ ni òun náà.”

14. Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó mú oúnjẹ ati omi sinu ìgò aláwọ kan, ó dì wọ́n fún Hagari, ó kó wọn kọ́ ọ léjìká, ó fa ọmọ rẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó ní kí wọn ó jáde kúrò nílé. Hagari jáde nílé, ó bá ń rìn káàkiri ninu aginjù Beeriṣeba.

15. Nígbà tí omi tán ninu ìgò aláwọ náà, Hagari fi ọmọ náà sílẹ̀ lábẹ́ igbó ṣúúrú kan tí ó wà níbẹ̀.

16. Ó lọ jókòó ní òkèèrè, ó takété sí i, ó tó ìwọ̀n ibi tí ọfà tí eniyan bá ta lè balẹ̀ sí, nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “Má jẹ́ kí n wo àtikú ọmọ mi.”

17. Bí ó ṣe jókòó tí ó takété sí ọmọ náà, ọmọ fi igbe ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ọlọrun gbọ́ igbe ọmọ náà, angẹli Ọlọrun bá ké sí Hagari láti ọ̀run wá, ó bi í pé, “Kí ni ó ń dààmú ọkàn rẹ, Hagari? Má bẹ̀rù, nítorí Ọlọrun ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí ó wà.

18. Dìde, lọ gbé e, kí o sì rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, nítorí n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 21