Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 19:20-36 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹ wò ó, ìlú tí ó wà lọ́hùn-ún nì súnmọ́ tòsí tó láti sálọ, ó sì tún jẹ́ ìlú kékeré. Ẹ jẹ́ kí n sálọ sibẹ, ṣebí ìlú kékeré ni? Ẹ̀mí mi yóo sì là.”

21. OLUWA dáhùn pé, “Ó dára, mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, n kò ní pa ìlú náà run.

22. Ṣe kíá, kí o sálọ sibẹ, nítorí n kò lè ṣe ohunkohun, títí tí o óo fi dé ibẹ̀.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ìlú náà ní Soari.

23. Oòrùn ti yọ nígbà tí Lọti dé Soari.

24. OLUWA bá rọ òjò imí ọjọ́ ati iná láti ọ̀run wá sórí Sodomu ati Gomora,

25. ó sì pa ìlú náà run ati gbogbo àfonífojì náà. Ó pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé àwọn ìlú náà run, ati gbogbo ohun tí ó hù lórí ilẹ̀.

26. Ṣugbọn aya Lọti tí ó wà lẹ́yìn ọkọ rẹ̀ wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ̀n iyọ̀.

27. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Abrahamu lọ sí ibi tí ó ti dúró níwájú OLUWA,

28. ó wo ìhà ibi tí Sodomu ati Gomora wà, ati gbogbo àfonífojì náà, ó rí i pé gbogbo rẹ̀ ń yọ èéfín bí iná ìléru ńlá.

29. Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun.

30. Nígbà tí ó yá, Lọti jáde kúrò ní Soari, nítorí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ibẹ̀, òun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji bá kó lọ sí orí òkè, wọ́n sì ń gbé inú ihò kan níbẹ̀.

31. Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò, ó ní, “Baba wa ń darúgbó lọ, kò sì sí ọkunrin kan tí yóo fẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn eniyan.

32. Wò ó! Jẹ́ kí á mú baba wa mu ọtí àmupara, kí á sì sùn lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè bá wa lòpọ̀, kí á le tipasẹ̀ rẹ̀ bímọ.”

33. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún baba wọn ní ọtí mu ní alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àkọ́bí wọlé lọ, ó sì mú kí baba wọ́n bá òun lòpọ̀, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde.

34. Ní ọjọ́ keji, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò pé, “Èmi ni mo sùn lọ́dọ̀ baba wa lánàá, jẹ́ kí á tún mú kí ó mu ọtí àmupara lálẹ́ òní, kí ìwọ náà lè wọlé tọ̀ ọ́ lọ, kí ó lè bá ọ lòpọ̀, kí á sì lè bímọ nípasẹ̀ baba wa.”

35. Wọ́n mú kí baba wọn mu ọtí waini ní alẹ́ ọjọ́ náà pẹlu, èyí àbúrò lọ sùn tì í, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde.

36. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lọti mejeeji ṣe lóyún fún baba wọn.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 19