Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 18:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ó wí pé, “Ẹ̀yin oluwa mi, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má kọjá lọ bẹ́ẹ̀ láìdúró díẹ̀ lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín!

4. Ẹ jẹ́ kí wọ́n bu omi wá kí ẹ fi ṣan ẹsẹ̀, kí ẹ sì sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi níhìn-ín.

5. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti yà lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín, ẹ kúkú jẹ́ kí n tètè tọ́jú oúnjẹ díẹ̀ fún yín láti jẹ, bí ẹ bá tilẹ̀ wá fẹ́ máa lọ nígbà náà, kò burú.”Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, lọ ṣe bí o ti wí.”

6. Abrahamu yára wọ inú àgọ́ tọ Sara lọ, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ tètè tọ́jú ìwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹta, bá mi yára pò ó, kí o fi ṣe àkàrà.”

7. Abrahamu tún yára lọ sinu agbo mààlúù rẹ̀, ó mú ọ̀dọ́ mààlúù kan tí ó lọ́ràá dáradára, ó fà á fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní kí wọ́n yára pa á, kí wọ́n sì sè é.

8. Ó mú wàràǹkàṣì, ati omi wàrà, ati ẹran ọ̀dọ́ mààlúù tí wọ́n sè, ó gbé wọn kalẹ̀ fún àwọn àlejò náà, ó sì dúró tì wọ́n bí wọ́n ti ń jẹun lábẹ́ igi.

9. Nígbà tí wọ́n jẹun tán, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Sara aya rẹ wà?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ninu àgọ́.”

10. Ọ̀kan ninu àwọn àlejò náà wí pé, “Dájúdájú, n óo pada tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara, aya rẹ yóo bí ọmọkunrin kan.”Sara fetí mọ́ ògiri lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ lẹ́yìn ibi tí àwọn àlejò náà wà, ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ.

11. Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn.

12. Nítorí náà, nígbà tí Sara gbọ́ pé òun óo bímọ, ó rẹ́rìn-ín sinu ara rẹ̀, ó ní, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó, tí ọkọ mi náà sì ti di arúgbó, ǹjẹ́ mo tilẹ̀ tún lè gbádùn oorun ọmọ bíbí?”

13. OLUWA bi Abrahamu pé, “Èéṣe tí Sara fi rẹ́rìn-ín, tí ó wí pé, ṣé lóòótọ́ ni òun óo bímọ lẹ́yìn tí òun ti darúgbó?

14. Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.”

15. Ẹ̀rù ba Sara, ó sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. OLUWA sọ pé, “Má purọ́! o rẹ́rìn-ín.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 18