Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 18:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọ̀sán gangan ọjọ́ kan, OLUWA fara han Abrahamu bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, lẹ́bàá igi Oaku ti Mamure.

2. Bí ó ti gbójú sókè, bẹ́ẹ̀ ni ó rí àwọn ọkunrin mẹta kan, wọ́n dúró ní ọ̀kánkán níwájú rẹ̀. Bí ó ti rí wọn, ó sáré lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn.

3. Ó wí pé, “Ẹ̀yin oluwa mi, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má kọjá lọ bẹ́ẹ̀ láìdúró díẹ̀ lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín!

4. Ẹ jẹ́ kí wọ́n bu omi wá kí ẹ fi ṣan ẹsẹ̀, kí ẹ sì sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi níhìn-ín.

5. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti yà lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín, ẹ kúkú jẹ́ kí n tètè tọ́jú oúnjẹ díẹ̀ fún yín láti jẹ, bí ẹ bá tilẹ̀ wá fẹ́ máa lọ nígbà náà, kò burú.”Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, lọ ṣe bí o ti wí.”

6. Abrahamu yára wọ inú àgọ́ tọ Sara lọ, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ tètè tọ́jú ìwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹta, bá mi yára pò ó, kí o fi ṣe àkàrà.”

7. Abrahamu tún yára lọ sinu agbo mààlúù rẹ̀, ó mú ọ̀dọ́ mààlúù kan tí ó lọ́ràá dáradára, ó fà á fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní kí wọ́n yára pa á, kí wọ́n sì sè é.

8. Ó mú wàràǹkàṣì, ati omi wàrà, ati ẹran ọ̀dọ́ mààlúù tí wọ́n sè, ó gbé wọn kalẹ̀ fún àwọn àlejò náà, ó sì dúró tì wọ́n bí wọ́n ti ń jẹun lábẹ́ igi.

9. Nígbà tí wọ́n jẹun tán, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Sara aya rẹ wà?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ninu àgọ́.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 18