Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 17:17-27 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?”

18. Abrahamu bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣá ti bá mi dá Iṣimaeli yìí sí.”

19. Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀.

20. Ní ti Iṣimaeli, mo ti gbọ́ ìbéèrè rẹ, wò ó, n óo bukun òun náà, n óo sì fún un ní ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ ọmọ, yóo jẹ́ baba fún àwọn ọba mejila, n óo sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá.

21. Ṣugbọn n óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu Isaaki, tí Sara yóo bí fún ọ ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀.”

22. Nígbà tí Ọlọrun bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

23. Abrahamu bá mú Iṣimaeli ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ẹrukunrin tí wọ́n bí ninu ilé rẹ̀ ati àwọn tí ó fi owó rẹ̀ rà, àní gbogbo ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé Abrahamu, ó sì kọ gbogbo wọn ní ilà abẹ́ ní ọjọ́ náà, bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un.

24. Abrahamu jẹ́ ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un nígbà tí ó kọ ilà abẹ́.

25. Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún mẹtala nígbà tí òun náà kọlà abẹ́.

26. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Abrahamu ati Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ kọlà abẹ́,

27. ati gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n fi owó rà, gbogbo wọn ni wọ́n kọ nílà abẹ́ pẹlu rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 17