Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 17:13-24 BIBELI MIMỌ (BM)

13. gbogbo ọmọ tí ẹ bí ninu ilé yín, ati ẹrú tí ẹ fi owó yín rà gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Èyí yóo jẹ́ kí majẹmu mi wà lára yín, yóo sì jẹ́ majẹmu ayérayé.

14. Gbogbo ọkunrin tí kò bá kọlà abẹ́ ni a óo yọ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ó ti ba majẹmu mi jẹ́.”

15. Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai aya rẹ, má ṣe pè é ní Sarai mọ́, Sara ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́.

16. N óo bukun un, n óo sì fún ọ ní ọmọkunrin kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, n óo bukun un, yóo sì di ìyá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo wà lára atọmọdọmọ rẹ̀.”

17. Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?”

18. Abrahamu bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣá ti bá mi dá Iṣimaeli yìí sí.”

19. Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀.

20. Ní ti Iṣimaeli, mo ti gbọ́ ìbéèrè rẹ, wò ó, n óo bukun òun náà, n óo sì fún un ní ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ ọmọ, yóo jẹ́ baba fún àwọn ọba mejila, n óo sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá.

21. Ṣugbọn n óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu Isaaki, tí Sara yóo bí fún ọ ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀.”

22. Nígbà tí Ọlọrun bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

23. Abrahamu bá mú Iṣimaeli ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ẹrukunrin tí wọ́n bí ninu ilé rẹ̀ ati àwọn tí ó fi owó rẹ̀ rà, àní gbogbo ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé Abrahamu, ó sì kọ gbogbo wọn ní ilà abẹ́ ní ọjọ́ náà, bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un.

24. Abrahamu jẹ́ ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un nígbà tí ó kọ ilà abẹ́.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 17