Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 14:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nígbà náà ni ọba Sodomu, ati ọba Gomora jáde lọ, pẹlu ọba Adima, ọba Seboimu, ati ọba Bela, (tí ó tún ń jẹ́, Soari). Wọ́n pa ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu.

9. Wọ́n gbógun ti Kedorilaomeri, ọba Elamu, Tidali, ọba Goiimu, Amrafeli, ọba Babiloni ati Arioku, ọba Elasari. Ọba mẹrin dojú kọ ọba marun-un.

10. Àfonífojì Sidimu kún fún ihò tí wọ́n ti wa ọ̀dà ilẹ̀. Bí àwọn ọmọ ogun ọba Sodomu ati àwọn ọmọ ogun ọba Gomora ti ń sálọ, àwọn kan ninu wọn jìn sinu àwọn ihò náà, àwọn yòókù sá gun orí òkè lọ.

11. Àwọn ọ̀tá kó gbogbo ẹrù ati oúnjẹ àwọn ará Sodomu ati Gomora, wọ́n bá tiwọn lọ.

12. Ọwọ́ wọn tẹ Lọti, ọmọ arakunrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu, wọ́n mú un lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ.

13. Nígbà náà ni ẹnìkan tí ó sá àsálà lójú ogun náà wá ròyìn fún Abramu, tí ó jẹ́ Heberu, tí ń gbé lẹ́bàá igi Oaku, ní igbó Mamure, ará Amori. Mamure ati àwọn arakunrin rẹ̀ Eṣikolu ati Aneri bá Abramu dá majẹmu.

14. Nígbà tí Abramu gbọ́ pé wọ́n ti mú ìbátan òun lẹ́rú, ó kó ọọdunrun ó lé mejidinlogun (318) ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, tí ó sì ti kọ́ ní ogun jíjà, ó lépa àwọn tí wọ́n mú Lọti lẹ́rú lọ títí dé ilẹ̀ Dani.

15. Ó pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ní òru ọjọ́ náà. Òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ yí àwọn ọ̀tá náà po, wọ́n ṣí wọn nídìí, wọ́n sì lépa wọn títí dé ìlú Hoba ní apá ìhà àríwá Damasku.

16. Abramu gba gbogbo ìkógun tí wọ́n kó pada, ó gba Lọti, ìbátan rẹ̀ pẹlu ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, ati àwọn obinrin ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan mìíràn.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 14