Nígbà tí Abramu ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n jọ pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Sodomu jáde lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (tí ó tún ń jẹ́, àfonífojì ọba).