Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 13:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde kúrò ní Ijipti, ó pada lọ sí Nẹgẹbu pẹlu aya rẹ̀, ati Lọti ati ohun gbogbo tí ó ní.

2. Abramu ní dúkìá pupọ ní àkókò yìí, ó ní ẹran ọ̀sìn, fadaka ati wúrà lọpọlọpọ.

3. Nígbà tí ó yá, ó kúrò ní Nẹgẹbu, ó ń lọ sí Bẹtẹli, ó dé ibi tí ó kọ́kọ́ pàgọ́ sí

4. láàrin Bẹtẹli ati Ai, níbi pẹpẹ tí ó kọ́kọ́ pa, ibẹ̀ ni ó sì ti sin OLUWA.

5. Lọti tí ó bá Abramu lọ náà ní ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo mààlúù ati ọpọlọpọ àgọ́ fún ìdílé rẹ̀ ati àwọn iranṣẹ rẹ̀.

6. Ẹran ọ̀sìn àwọn mejeeji pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ náà kò fi láàyè tó mọ́ fún wọn láti jọ máa gbé pọ̀.

7. Ìjà sì ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn darandaran Abramu ati àwọn ti Lọti. Ní àkókò náà, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi ń gbé ilẹ̀ náà.

8. Abramu bá sọ fún Lọti pé, “Má jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, tabi láàrin àwọn darandaran mi ati àwọn tìrẹ. Ṣebí ara kan náà ni wá?

9. Ilẹ̀ ló lọ jaburata níwájú rẹ yìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á takété sí ara wa. Bí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún, bí o bá sì lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.”

10. Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run.

11. Lọti bá yan gbogbo agbègbè odò Jọdani fún ara rẹ̀, ó sì lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe takété sí ara wọn.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 13